Afe Babalola àti Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Afe Babalola/Dele Farotimi/Facebook

Lonii, ọjọ Kẹtala, oṣu Kiini ọdun 2025, ni igbẹjọ foriti sibikan lori ẹsun ibanilorukọ jẹ to wa laarin agbẹjọro to tun jẹ onkowe nii, Dele Farotimi ati Afe Babalola(SAN).

Nile ẹjọ magisreeti ti ilu Ado Ekiti ni Adajọ Abayomi Adeosun, to lewaju fun igbẹjọ naa ti sọ wipe gbogbo ọrọ naa ti wa sopin ni Ile ẹjọ.

Ijoko igbẹjọ naa bẹrẹ lọwọ aago mẹsan-an owurọ,

Dele Farotimi ati awọn agbẹjọro tiẹ naa wa nikalẹ, wọn si pari igbẹjọ naa laarin iṣẹju perete.

Tẹẹ ba gbagbe wipe ni oṣu kejila ọdun 2024, ni ile iṣẹ ọlọpaa gbe Dele Farotimi lọ sile ẹjọ.

Lẹyin tiwon tẹwọ gba iwe ifẹsunkani ti Afe Babalola kọ tako o nitori agbejade iwe kan ti akori rẹ njẹ “Nigeria and it’s criminal justice system”.

Loni ni Adajọ Abayomi Adeosun, pa oju ẹjọ naa de.

Samson Osubo, ọlọpaa oluwoni rele ẹjọ kan, kọwe siwaju kootu ọun wipe Afe Babalola ti jawọ ninu igbẹjọ naa.

Agbẹjọro Kembi Adejare, to n soju fun Dele Farotimi nile ẹjọ, sọfun oniroyin BBC Yoruba wipe, lootọ ni ile ẹjọ ti figi gun ẹjọ naa loju, leyin ti olujejọ o ti loun ko sẹjọ mọ.

Igbẹjọ pari lẹyin isẹju bii mẹwa, a si ri Dele Farotimi to wọ inu ọkọ rẹ lai boniroyin sọ ohunkohun.

N kò bá Dele Farotimi ṣe ẹjọ́ mọ́, kò sí ohun tí mo fẹ́ gbà tó bá lọ sẹ́wọ̀n – Afe Babalola

Agba Amofin ati Oludasilẹ fasiti nilu Ado Ekiti, Aare Afe Babalola ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan laarin oun ati amofin ajafẹtọẹni nni, Dele Farotimi.

Bakan naa, Afe Babalola kede pe oun ti jami lori ẹjọ ẹsun iwa ọdaran ti oun pe amofin ajafẹtọẹni naa.

Ikede ipari ija ọhun lo waye nibi ipade awọn akọroyin kan lọjọ Aiku nilu Ado Ekiti nibi ti Ooni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi peju si pẹlu awọn oriade ati agbaagba miran nilẹ Yoruba.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Afe Babalola lo figbe ta laipẹ yii pe Dele Farotimi ta epo si asọ ala oun, to si gbe lọ sile ẹjọ.

“Mo kọ lati gba kanga epo rọbi, mose atilẹyin fun ofin ajọ EFCC, mo kọ lati gba ipo Minisita ni ẹẹmeji, eeyan kan ko le tẹmbẹlu gbogbo ohun ti mo se laalaa fun”

Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin naa, Afẹ Babalola ni oun pinnu lati jami lori ẹjọ to pe agbẹjẹro Dele Farotimi nitori bi Ooni Ogunwusi, Ewi tilu Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adejugbe ati awọn oriade miran yika Naijiria se da si aawọ naa.

Aare Babalola ni oun ti kọkọ kọ ẹyin sawọn oriade atawọn eeyan jankajankan miran, to da si aawọ naa saaju yika orilẹede yii ati lẹyin odi.

Amọ o ni oun ko gbọdọ tapa sawọn oriade nitori lati igba iwasẹ, asẹ ni ọba maa n pa, ọba kii daba.

“Mo ti kọ lati gba kanga epo rọbi, ti mo si se atilẹyin fun ofin ajọ EFCC, bakan naa, mo kọ lati gba ipo Minisita ni ẹẹmeji, amọ iyalẹnu lo jẹ fun mi pe eeyan kan yoo kan dide lọjọ kan lati tẹmbẹlu gbogbo awọn ohun ti mo se laalaa le lori.”

Afe Babalola, bi a ba fi ọwọ ọtun ba ọmọ wi nilẹ Yoruba, a maa n fi ọwọ osi fa mọra ni – Ooni

Nigba toun naa n bawọn akọroyin sọrọ, Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Keji tun rawọ ẹbẹ si Afe Babalola pe ko wo ti gbogbo awọn eekanlu to ti da si aawọ naa, ko si jeburẹ.

Oriade naa wa yonbo Afe Babalola lori ọpọ ipa to n ko si idagbasoke iran Yoruba, orilẹede Naijiria ati awujọ agbaye lapapọ.

“Gbogbo wa pejọ lati jiroro lori isẹlẹ yii pẹlu Afe Babalola, to si bọwọ nla fun wa gẹgẹ bi ọba alaye, to si gba ẹbẹ wa yẹwo.

A le fọwọ gbaya nipa isẹ nla ti Afe Babalola n se ati bo se saayan lati wa orukọ rere fun ara rẹ eyi ti yoo nira fun ẹnikẹni lati ta epo si asọ ala rẹ.

Aare Afe Babalola ti fidi rẹ mulẹ fun gbogbo aye bayi pe oun mọ riri orukọ oun, ti gbogbo aye naa si ti gbọ ọ ni agbọye.

Ọmọ rẹ ni Dele Farotimi, oniruuru ọmọ ni a maa n bi nile aye, gẹgẹ bi agbalagba, tawọn ọmọ wa ba sẹ wa nilẹ Yoruba, ti a ba fi ọwọ ọtun ba wi, a si tun fi ọwọ osi fa a mọra”.

Awọn oriade miran to tun peju sibi ipade akọroyin naa ni Ewi ti Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe, Olojudo ti Ido-Ekiti, Oba Ilori Faboro, Ogoga ti Ikere-Ekiti, Oba Adejimi Alagbado, ati Oloye tilu Oye-Ekiti, Oba Michael Ademolaju.

Ki lo fa aawọ laarin Afe Babalola ati Dele Farotimi?

Ni bii osu melo kan ni ariwo ta yika Naijiria pe agba amofin Afe Babalola n binu, to si n fapa janu pe amofin miran, to filu Eko se ibujoko, Dele Farotimi, ta ẹrẹ si asọ aala oun.

Afẹ ni ninu iwe kan ti Farotimi kọ, eyo ti pe ni “Nigeria and its Criminal Justice System” lo ti fi ẹsun kan Afe Babalola pe sọ ẹka eto idajọ Naijiria di alajẹbanu ati onijẹkujẹ.

Idi si ree ti Afe Babalola fi wọ Farotimi lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ to wa ninu iwe to gbe sita ati bo se ta epo si asọ aala rẹ.